|
HapMap yio jẹ
akojọpọ awọn ibiti jiini awa ẹda ti yatọ si ara
wọn. Yio şe apejuwe wọn, ibiti wọn wa ninu DNA, ati bi
wọn ti se yatọ si lati ẹya si ẹya kakiri gbogbo agbaye.
Ninu iwadi yi, a ko ni wa ọna ti iyatọ ki iyatọ ti o ba wa
ninu jiini şe toro mọ aisan. Ohun ti iwadi yi yio gbe jade yio ran
awọn ọjọgbọn miran lọwọ lati şe iru
iwadi wọnwọnyi. Eleyi yio jẹki awọn oluwadi miran le
şe awari ọna titun lati dena, şe iwadi ati lati şe itoju
orişirişi aisan.
 |
| Aworan Kinni: Ti a ba fi ara akaşu-jiini (chromosome) keje lati ẹni mẹji ti wọn ko
jọra wọn we ara wọn, a o ri wipe wọn yatọ ni dede
ọkan larin ẹgbẹrun le ni okoo nukuleotaidi (nucleotide) |
Orişi nukuleotaidi
mẹrin lo wa - adenine, thymine, cytosine, ati guanine, ti inagijẹ
wọn si njẹ A, T, C, ati G. Ẹgbẹgbẹrun awọn
nukuleotaidi wọnyi ti a so pọ gẹgẹbi akaşu-jiini
ni won wa ninu ẹya ara ti o kere julọ ti a npe ni Sẹli (cell). Akaşu-jiini
ti o si wa ninu ara jẹ mẹtalelogun. (Ẹ wo
<http://www.dnaftb.org/dnaftb/ fun alaye tio peye lori eleyi). Asopọ jiini wọnyi ni o ndari bi a
ti şe ri gẹgẹbi ọmọ eniyan, boya aisan kan tabi
omiran yio şe wa, ati bi ara wa şe nba ibugbe (environment) wa lo pọ.
Asopọ jiini ara awa ọmọ eniyan jọra
lọpọlọpọ. Bi a ba fi ti ẹnimeji we ara wọn,
a o ri wipe, wọn jọ ara wọn gan. Amọ ni deede iko kan larin ọgọrun
mejila, a o ri iyatọ kan kan (Aworan Kinni). Ni ibiti iyatọ wa
wọnyi, ẹnikan le ni, A, ki ẹnikeji ni G, lojukanna; tabi ki
ẹnikan ni nukuleotaidi tayọ ẹnikeji; tabi ki o ma ni to ti
ẹnikeji. Nigbati a ba ni iwọn jiini ti o yatọ si ara
wọn gẹgẹbi a ti se apẹrẹ yi, eleyi ni a npe ni
Òẹda-jiiniÓ (allele). Agbajọ ẹda-jiini olukaluku ni a npe ni ayanmọ-jiini (genotype)
Awọn kooko ibiti
iyatọ wa ninu jiini ni a npe ni siniipu (Single Nucleotide
Polymorphisms(SNPs)), awọn si ni iyatọ ti o
wọpọ ju ninu ayanmọ-jiini. Erogba ilana iwadi HapMap yi ni
lati ni imọ ti o peye lori ẹgbẹgbẹrun lọna
mẹwa siniipu ti o wa ninu ayanmọ-jiini ẹda.
Fun awọn
ọjọgbọn ninu imo aisan ajogunba, siniipu jẹ ami ti a le
fi wa jiini ninu akojọpọ (sequences) wọn. Fun
apẹrẹ, ti iyatọ ba wa ninu jiini, ti iyatọ yi si
dirọ mọ aisan ẹjẹ ruru, ti awọn
ọjọgbọn ko si mọ dede ibiti iyatọ yi wa,
wọn le şe iwadi, ki wọn fi siniipu awọn ẹniti o ni
aisan yi we ti awọn ẹniti ko nii. Eleyi yio şe atọka
dede ibiti irufẹ jiini bẹ wa fun wọn.
Amọ, şise iwadi
lori gbogbo siniipu ti o wa lara ẹda, a na ni lowo
lọpọlọpọ. Iwadi HapMap yio gbe ilana titun jade ti yio
jẹ ki awọn ọjọgbọn le lo awọn siniipu ati
iyatọ orisirisi miran ti o wa ninu jiini. A ri wipe nşe ni awa
ẹda ma njogun awọn iyatọ wọnyi lapapọ ni.
Awọn ti wọn ba ni "A" ni gbagede kan, wọn a ma saba ni "G" ni
gbagede ti o ba sun mọ ọ. A le wa ri wipe ti a ba şa gbogbo
awọn ti wọn ni "A", iru siniipu kanna ni wọn ma ni ni gbagede miran. Deede ibiti awọn
siniipu ara jiini ba ti jọ ara wọn bayi ni a npe ni
iwọn-jiini (haplotype). (Aworan Keji)
A şe akiyesi wipe a le pin akaşu-jiini ara enia si iwọnba
iwọn-jiini melo kan. [Ẹ tẹ ikanna yin mọ ibiyi lati ni
imọ si nipa işẹdalẹ iwọn-jiini.] Ninu
ẹyakẹya, dede ida mọkanla-ninu-ogun awọn enia, a ni
irufẹ iwọn-jiini kan, nigbati awọn ida mẹfa-ninu-ogun
yi a ni iru omiran, ti ida bi meji-ninu-ogun o din siun, a si ni irukẹta.
Awọn yoku yio ni irufẹ iwọn-jiini ti ko wọpọ
rara. Awọn eyiti o wọpọ ninu iwọn-jiini yi ni Ilana
HapMap nşe iwadi le lori lara awọn ẹya mẹrin jakejado
gbogbo agbaye. Botilẹ je wipe akaşu-jiini kan ni
ọpọlọpọ siniipu, awọn siniipu-alapẹrẹ
(tag SNP) kankan
to lati tu aşiri iru iyatọ ti o wa ninu akaşu-jiini bawọn
yi. Ọna ti a ngba şe awari awọn siniipu-alapẹrẹ ni
awọn oloyinbo npe ni genotyping. Ọna yi yio fun wa ni anfani lati
mọ iye siniipu-alapẹrẹ ti o wa lara ẹda.
Ni were ti a ba ti ni imọ
nipa awọn siniipu-alapẹrẹ wọnyi, awọn
ọjọgbọn yio le lo wọn lati wa ibiti awọn jiini ti o
ni şe pẹlu aisan wa. Fun apẹrẹ, ti oluwadi kan ba
fẹ mọ iru iyatọ ti o wa lara jiini ti o si ni şi şe
pẹlu aisan ẹjẹ ruru, kaka ki o ma wa gbogbo siniipu ti o wa
lara awọn eniti o nşe iwadi le lori, yio kan mu awọn siniipu-alapẹrẹ lo
ni, eleyi ko ni gba lakoko tabi inawo to ilana ti o wa nisisinsiyi.
|